Dyana Gaye

Dyana Gaye
Ọjọ́ìbí1975 (ọmọ ọdún 48–49)
Paris
Orílẹ̀-èdèFrench-Senegalese
Iṣẹ́Film director
Ìgbà iṣẹ́2000-present

Dyana Gaye (tí wọ́n bí ní ọdún 1975) jẹ́ olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Fráǹsì àti Sẹ́nẹ́gàl

Wọ́n bí Gaye ní ìlú Paris, orílẹ̀-èdè Fráǹsì ní ọdún 1975. Ó jẹ́ ọmọ àwọn òbí tí wọ́n ti orílẹ̀-èdè ṣẹ́nẹ́gàl wá sí Fráǹsì. Gaye kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ fíìmù ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Paris 8 Vincennes-Saint-Denis.[1] Ó gba ẹ̀bùn ìrànlọ́wọ́ kan láti ọwọ́ Louis Lumière - Villa Médicis ní ọdún 1999 fún ìtàn-eré rẹ̀ tí ó kọ táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní Une femme pour Souleymane.[2] Gaye náà ló ṣe adarí nígbà tí wọ́n fi n ṣiṣẹ́ láti gbé eré náà jáde ní ọdún 2000, eré náà síì gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Dakar Film Festival.[3] Ní ọdún 2004, ó kópa níbi àṣekágbá ti ètò Rolex Mentor and Protégé Arts Initiative. Gaye darí fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ J'ai deux amours ní ìlànà pẹ̀lú iṣẹ́ àkànṣe kan tí wọ́n pẹ̀ ní Paris la métisse ní ọdún 2005. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó ṣe adarí fún ti eré Ousmane, èyítí wọ́n ṣe ní àṣeyege. Wọ́n yaan eré náà fún àmì-ẹ̀yẹ eré oníṣókí tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ César Awards. Ní ọdún 2009, Gaye tún ṣe olùgbéréjáde àti olùdarí eré aláwàdà kan tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Saint Louis Blues. Wọ́n tún yaan eré ọ̀ún náà fún àmì-ẹ̀yẹ eré oníṣókí tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ César Awards bákan náà.[4] Ààjọ kan tí wọ́n pè ní Focus Features Africa ni ó ṣe onígbọ̀wọ́ ètó náà.[5]

Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Gan Foundation Creation Prize ní ọdún 2012.[6] Gaye darí fíìmù Under the Starry Sky ní ọdún 2013, tó sì di àkọ́kọ́ fíìmù gígùn tí wọ́n gbéṣe ní ìlú Dakar, Turin, àti New York. Fíìmù náà jẹ́ wíwò níbi ayẹyẹ Toronto International Film Festival, ó sì tún gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ méjì kan níbi ayẹyẹ Premiers Plans Angers Festival. Gaye ṣàpèjúwe fíìmù náà gẹ́gẹ́bi ìtẹ̀síwájú àwọn fíìmù oníṣókí tí òún ti ṣe tẹ́lẹ̀.[7]

Gaye jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Collectif 50/50, ẹgbẹ́ kan tí ó fẹ́ láti ri dájú wípé ìdọ́gba wà láàrin àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní agbo òṣèré fíìmù.[8]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 2000 : Une femme pour Souleymane
  • 2005 : J’ai deux amours
  • 2006 : Ousmane
  • 2009 : Saint Louis Blues
  • 2013 : Under the Starry Sky
  • 2014 : Un conte de la Goutte d'or

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Biografie Dyana Gaye". Filme Aus Afrika. Archived from the original on 7 May 2021. Retrieved 19 October 2020. 
  2. "Dyana Gaye Biography". African Film Festival New York. Retrieved 18 October 2020. 
  3. "Dyana Gaye 2012 Laureate". Gan Foundation. Retrieved 18 October 2020. 
  4. "Dyana Gaye Biography". African Film Festival New York. Retrieved 18 October 2020. 
  5. "Focus Features Africa First Alumni Dyana Gaye Will Make Her Feature Film Debut With "Des Etoiles" ("Stars")". Shadow and Act. 20 April 2017. Retrieved 18 October 2020. 
  6. "Dyana Gaye 2012 Laureate". Gan Foundation. Retrieved 18 October 2020. 
  7. Walsh, David (2 October 2013). "An interview with Dyana Gaye, director of Under the Starry Sky". World Socialist Web Site. Retrieved 19 October 2020. 
  8. "Dyana Gaye Biography". African Film Festival New York. Retrieved 18 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]