Jude Dibia (tí wọ́n bí ní 5 January 1975 ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ní Nàìjíríà) jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ní ọdún 2007, ó gba ẹ̀bù ti Ken Saro-Wiwa fún ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Unbridled.
Dibia kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, ó sì gboyè B.A. nínú ẹ̀kọ́ Modern European Languages (German).
Àwọn ìwé-ìtàn àròsọ Jude ni wọ́n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí i èyí tó jẹ mọ́ onígboyànínú àti àríyànjiyàn láti ọẃ àwọn òǹkàwé àti alárìíwísí ìwé náà káàkiri ilẹ̀ Africa. Walking with Shadows ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìwẹ́ ìtàn-àròsọ ilẹ̀ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó máa ní ọkùnrin tó jẹ́ géè nínú, tí ó sì tún jẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn. Unbridled, náà, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí àti àríyànjiyàn; ó jẹ́ ìtàn tó dojú ìkà kọ àwọn tó ń fìyà jẹ obìnrin, tí ó ti ní ìrírí mọ̀lẹ́bí tí ń bánilòpọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjìyà lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin.[2]
Wọ́n ti ṣàfihàn àwọn ìtàn kékeré Dibia lórí ẹ̀rọ-ayélujára bí i AfricanWriter.com àti Halftribe.com. Ọ̀kan lára àwọn ìtàn kékeré rẹ̀ ni One World: tó jẹ́ àkójọpọ̀ ìtàn kékeré bí i ti Chimamanda Ngozi Adichie àti Jhumpa Lahiri.[3]