Tosyn Bucknor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Olúwatósìn Bucknor 15 Oṣù Kẹjọ 1981 Ìpínlẹ̀ Èkó, Nigeria |
Aláìsí | 19 November 2018 | (ọmọ ọdún 37)
Orúkọ míràn | Tosyn Bucknor |
Iṣẹ́ | Agbòhùnsáfẹ́fẹ́ Òṣèrébìnrin |
Ìgbà iṣẹ́ | 2009–2018 |
Olólùfẹ́ | Aurélien Boyer (m. 2015–2018) |
Olúwatósìn Bucknor tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tosyn Bucknor tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1981,ó sìn ta téru nípàá lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2018 (15 August 1981 – 19 November 2018), jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Òṣèrébìnrin àti gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí ìtàkùn abánidọ́rẹ̀ẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1][2]
Wọ́n bí Tosyn sí ìdílé gbajúmọ̀ olórin, Ọ̀gbẹ́ni ṣẹ́gun Bucknor àti Ìyáàfin ṣọlá Bucknor. Inú ọkọ̀ ni wọ́n bí i sí lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ọdún 1981.[3] Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ni gbajúgbajà abániṣètò ètò, Fúnkẹ́ Bucknor-Obruthe, Aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ Zapphaire Events.
Tosyn kàwé ní Fountain Nursery and Primary School, Queens' College, Yaba, University of Lagos (LLB) àti the Nigerian Law School, ní ìpínlè Èkó. Ó sin ilẹ̀ baba rẹ̀, National Youth Service Corps ní Port Harcourt, níbi tí ó ti kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Lítírésọ̀ èdè òyìnbó àti èdè Òyìnbó ní Archdeacon Crowther Memorial Girls' School, Elelenwo.
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rédíò pẹ̀lú Tee-A lórí ìkànnì Èkó 89.7fm, lẹ́yìn èyí, ó ṣiṣẹ́-kọ́ṣẹ́ (internship) ní Cool 96.9fm níbi tí ó ti ṣe atọ́kùn ètò Fun Hour Show on Saturdays. Nígbà ìsìnlù rẹ̀ lọ́dún 2009, Tosyn ni atọ́kùn ètò ààrọ̀ lórí ìkànnì rédíò 90.9fm. Òun nìkan ni atọ́kùn lórí ètò náà.
Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmìn-ẹ̀yẹ, tí wọ́n sìn tún ti yàn án fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn, lára wọn ni: Future Awards, ELOY Awards, Best of Nollywood awards àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Tosyn, nígbà ayé rẹ̀ jẹ́ olórin àti akọ̀wé orin ìgbàlódé. Àwo orin kan péré Pop Rock Soul and Jara ló gbé jáde.
Méjì nínú àwọn orin rẹ̀ ni wọn lò fún sinimá àgbéléwò kúkúrú Ìrètí. Ó kọrin, kọ̀wé orin àti ṣe akálẹ̀ orin gẹ́gẹ́ bí CON.tra.diction.
Tosyn ti bá àwọn gbajúmọ̀ olórin bíi Skales, Rooftop MCs àti Eva, Sess, Tintin, Coldflames, Dj Klem, Knighthouse, Micworx àti Cobhams ṣíṣe.
Tosyn tí ṣe atọ́kùn ètò tí ó pè ní Tosyns Buzz Live lórí ìkànnì Pulse TV ní gbogbo ọjọ́ Ẹ̀tì. Lára àwọn eré àti àwọn ètò tí ó ti kópa nínú Tẹlifíṣọ̀n ni:
Tosyn tí kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àti ìròyìn ìtakùrọ̀ lórí ìkànnì òníròyin àti Tẹlifíṣọ̀n ; lára wọn ni: