Omoba Yẹmí Ajíbádé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adéyẹmí Ọlánrewájú Goodman Ajíbádé 28 Oṣù Keje 1929 Ìlá Ọ̀ràngún, Ìpínlẹ̀ Ọ̀Ṣun, Nàìjíríà |
Aláìsí | 24 January 2013 London, UK | (ọmọ ọdún 83)
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Olùkọ̀tàn, òṣèré orí-ìtàgé àti olùdarí eré |
Notable work | Parcel Post Waiting for Hannibal |
Yẹmí Ajíbádé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Keje ọdún 1929. [1][2] – 24 January 2013[3]), Ẹni tí wọ́n mọ̀ sí Yẹmí Ajíbádé, Yẹmí Goodman Ajíbádé tàbí Adéyẹmí Ajíbádé, jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, adarí-eré, ati olùkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè England láti ọdún 1950. Ó ti kó ipa ribiribi nínú eré orí-ìtàgé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pàá pàá jùlọ Canon of Black drama. Ó ti kọ orísiríṣi eré, ó sì ti darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré pẹ̀lú lórí ẹ̀rọamóhùnmáwòrá, orí rédíò àti sinimá.
Adéyẹmí Ọlánrewájú Goodman Ajíbádé ni wọ́n bí ní ìdílé Ọba ní ìlú Ìlá Ọ̀ràngún ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun [4]Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ti Girama ti ìlú Abẹ́òkúta tí ó sì tú kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Kennington College of Law and Commerce ní ìlú London ní ọdún 1955. Ó tún kàwé ní ilé-ẹ̀kọ́ ti The Actors' Workshop ní ọdún 1960, ó sì tún kẹ́kọ́ ní London Film school ní ọdún 1966 àti London School of Gilm Technique ní ọdún. [1][5]
Nígbà tí ó wà ní ìlú UK, Ajíbádé kópa nínú eré orí rédíò fún ilé -iṣè ìgbóhùn-sáfẹ́gẹ́ BBC African Service. [6] Wọ́n ṣàfihàn Ajíbádé gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gòkè agbà nínú eré ìtàgé lọ́jọ́ iwájú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀[4] Òun ati olùkópa mìíràn bíi: Yulisa Amadu Maddy, Leslie Palmer, Eddie Tagoe, Karene Wallace, Basil Wanzira, and Elvania Zirimu, àti àwọn mìíràn tí wọ́n jọ ń kópa nínú eré ọlọ́kan-ò-jọ̀kan lóríbíi: ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ Lindsay Barrett Blackblast! ní ọdún 1973 fún isẹ́ pàtàkì ti BBC Two arts Full House ìtàn tí ó jẹ́ ti olùkọ̀tàn ará ikẹ̀ India.[7][8][9] Iṣẹ́ Ajíbádé ṣàfihan akitiyan rẹ̀ lórí iṣẹ́ rẹ̀ ń já fíkán pàá pàá jùlọ lórí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán, lára àwọn eré tí ó tún ń ṣe ni: Armchair Theatre "The Chocolate Tree" by Andrew Sinclair ní ọdún 1963,òun àti Earl Cameron pẹ̀lú Peter McEnery),[10] Danger Man ní ọdún (1965), Dixon of Dock Green ní ọdún (1968), Douglas Botting The Black Safari ní ọdún (1972), The Fosters ní ọdún (1976), Prisoners of Conscience ní ọdún (1981), àti Silent Witness ní ọdún(1996), and work on the stage – for instance, in "Plays Umbrella". Ó tún kópa nínú àwọn eré orí-ìtàgé sinimá mìíràn pẹ̀lú.[11][12][13][14] àti ní Lorraine Hansberry Les Blancs (Royal Exchange Theatre ní ọdún 2001.[15] Ó tún kópa gẹ́gẹ́ bí Terence Fisher nínú eré The Devil Rides Out ní ọdún 1968, gẹ́gẹ́ bí Monte Hellman nínú Shatter ní ọdún 1974 [16] gẹ́gẹ́ bí Hanif Kureshi nínú eré London Kills Me ní ọdún 1991 àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [17] Ní ọdún 1966, Ajíbádé darí àwọn òṣèré bíi tirẹ̀ nínú àpérò World Festival of Black Arts ní ìlú Dakar, tí ó jẹ́ olú-ìlú fún orílẹ̀-èdè Senegal, láti dqrí eré ònkọ̀tàn Obi Egbuna tí ó pè ní Wind Versus Polygamy; ní 2nd World Black Arts Festival ní Ìpínlẹ̀ Èkó